[Script Info] Title: [Events] Format: Layer, Start, End, Style, Name, MarginL, MarginR, MarginV, Effect, Text Dialogue: 0,0:00:01.56,0:00:04.14,Default,,0000,0000,0000,,Ọ̀rọ̀ ńlá rèé o Dialogue: 0,0:00:04.38,0:00:06.65,Default,,0000,0000,0000,,Orúkọ mi ni Greta Thunberg Dialogue: 0,0:00:06.85,0:00:10.21,Default,,0000,0000,0000,,Ní àkókò wa yìí, ọ̀pọ̀ nǹkan ti bẹ̀rẹ̀ sí í pa run Dialogue: 0,0:00:11.17,0:00:13.61,Default,,0000,0000,0000,,Afẹ́fẹ́ àti àyíká wa ń bà jẹ́ Dialogue: 0,0:00:14.02,0:00:18.22,Default,,0000,0000,0000,,Àwọn ọmọdé bíi tèmi pa ẹ̀kọ́ ìwé tì láti wọdé. Dialogue: 0,0:00:18.56,0:00:20.90,Default,,0000,0000,0000,,A ṣì lè tún ohun tó ti bà jẹ́ ṣe. Dialogue: 0,0:00:20.90,0:00:22.96,Default,,0000,0000,0000,,Ìwọ náà lè tún un ṣe. Dialogue: 0,0:00:23.37,0:00:26.58,Default,,0000,0000,0000,,Tá ò bá fẹ́ kí aráyé pa run, a gbọ́dọ̀ jáwọ́ nínú sísun epo rọ̀bì, àmọ́ ìyẹn nìkan ò tó. Dialogue: 0,0:00:27.22,0:00:29.82,Default,,0000,0000,0000,,Ọ̀pọ̀ àbá ni àwọn èèyàn ti dá, àmọ́ ojútùú kan wà fún wa. Dialogue: 0,0:00:30.11,0:00:32.69,Default,,0000,0000,0000,,wa Dialogue: 0,0:00:32.69,0:00:35.41,Default,,0000,0000,0000,,Ẹ jẹ́ kí ọ̀rẹ́ mi George ṣàlàyé. Dialogue: 0,0:00:35.68,0:00:38.11,Default,,0000,0000,0000,,Ẹ̀rọ ńlá kan wà tó máa ń fa èròjà carbon kúrò nínú afẹ́fẹ́, owó rẹ̀ ò pọ̀, ó sì máa ń tún Dialogue: 0,0:00:38.21,0:00:42.72,Default,,0000,0000,0000,,ara rẹ̀ ṣe Dialogue: 0,0:00:42.72,0:00:44.42,Default,,0000,0000,0000,,Òun là ń pè ní ... igi. Dialogue: 0,0:00:44.42,0:00:46.47,Default,,0000,0000,0000,,Igi jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó dá a jù láti fi tún afẹ́fẹ́ ṣe. Dialogue: 0,0:00:46.58,0:00:47.93,Default,,0000,0000,0000,,Àwọn igi ẹ̀gbà, koríko tó ti kú, igbó ńlá, ilẹ̀ pọ̀tọ̀pọ́tọ́, ìsàlẹ̀ òkun, igbó tí koríko bò, irà, òkìtì iyùn inú òkun Dialogue: 0,0:00:47.93,0:00:48.87,Default,,0000,0000,0000,,gbogbo wọn ló ń bá wa fa èròjà carbon kúrò nínú afẹ́fẹ́ Dialogue: 0,0:00:48.95,0:00:53.69,Default,,0000,0000,0000,,Igbó fúnra rẹ̀ ní ohun tó lè bá wa tún afẹ́fẹ́ tó ti bà jẹ́ ṣe. Dialogue: 0,0:00:53.69,0:00:56.50,Default,,0000,0000,0000,,Tá a bá jẹ́ kí igi àti afẹ́fẹ́ tún àyíká ṣe, àá rí ìyàtọ̀ ńlá. Dialogue: 0,0:00:56.50,0:00:58.77,Default,,0000,0000,0000,,Ìyẹn dáa, àbí bẹ́ẹ̀kọ́? Dialogue: 0,0:00:58.77,0:01:02.69,Default,,0000,0000,0000,,Kí ìyẹn tó lè ṣẹlẹ̀, àfi ká fi epo rọ̀bì sàyẹ̀ rẹ̀ nínú ilẹ̀. Dialogue: 0,0:01:03.21,0:01:07.88,Default,,0000,0000,0000,,Àmọ́ ohun to yani lẹ́nu ni pé ... a ò ṣe ohun tó yẹ ká ṣe Dialogue: 0,0:01:08.50,0:01:12.32,Default,,0000,0000,0000,,Owó tí à ń ná lórí ìrànwọ́ fún wíwa epo rọ̀bì fi ìlọ́po ẹgbẹ̀rún ju owó tá a fi ń wá Dialogue: 0,0:01:12.32,0:01:14.01,Default,,0000,0000,0000,,ojútùú lọ. Dialogue: 0,0:01:14.22,0:01:17.62,Default,,0000,0000,0000,,Ìdá méjì nínú ọgọ́rùn-ún péré là ń ná Dialogue: 0,0:01:19.70,0:01:21.89,Default,,0000,0000,0000,,nínú gbogbo owó ìrànwọ́ láti fi wá ojútùú sí afẹ́fẹ́ tó ń bà jẹ́. Dialogue: 0,0:01:21.89,0:01:24.40,Default,,0000,0000,0000,, Dialogue: 0,0:01:25.74,0:01:30.55,Default,,0000,0000,0000,,Owó ẹ, owó orí ẹ àti èyí tí ò ń fi pa mọ́ wà lára owó yìí. Dialogue: 0,0:01:30.55,0:01:32.84,Default,,0000,0000,0000,,Ibi tí ọ̀rọ̀ wa ni pé ìsinsìnyí gan-an la nílò igi, afẹ́fẹ́ àti àyíká wa jù Dialogue: 0,0:01:32.84,0:01:35.38,Default,,0000,0000,0000,,àmọ́ ńṣe ni àwọn nǹkan yìí ń bà jẹ́ lọ́nà tó yára kánkán Dialogue: 0,0:01:35.38,0:01:39.05,Default,,0000,0000,0000,,Ó tó igba (200) ẹ̀dá abẹ̀mí tó ń pa run lójoojúmọ́ Dialogue: 0,0:01:39.39,0:01:41.02,Default,,0000,0000,0000,,Òkìtì yìnyín ńlá tó wà nípẹ̀kun ayé tí fẹ́rẹ̀ẹ́ yọ́ tán Dialogue: 0,0:01:41.02,0:01:43.47,Default,,0000,0000,0000,,Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹranko inú igbó ti kú tán Dialogue: 0,0:01:43.77,0:01:44.96,Default,,0000,0000,0000,,Ọ̀pọ̀lọ̀pọ ilẹ̀ ló ti bà jẹ́. Dialogue: 0,0:01:44.96,0:01:47.21,Default,,0000,0000,0000,,Kí ló yẹ ká ṣe? Dialogue: 0,0:01:47.21,0:01:50.09,Default,,0000,0000,0000,,Kí ni ìwọ lè ṣe? Dialogue: 0,0:01:50.09,0:01:54.23,Default,,0000,0000,0000,,Kò le rárá ... a ní láti dáàbò ohun tó ń bà jẹ́, ká tún un ṣe, ká sì fowó ṣètìlẹ́yìn. Dialogue: 0,0:01:54.46,0:01:57.05,Default,,0000,0000,0000,,Dáàbò bò ó. Dialogue: 0,0:01:57.05,0:01:59.03,Default,,0000,0000,0000,,Iye àwọn igbó tó wà nílẹ̀ olóoru tí à ń gé Dialogue: 0,0:01:59.03,0:02:01.01,Default,,0000,0000,0000,,láàárín ìṣẹ́jú kan tó ọgbọ̀n (30) pápá bọ́ọ̀lù. Dialogue: 0,0:02:01.01,0:02:02.81,Default,,0000,0000,0000,,Àwọn igbó yìí ń ṣe wá lóore, ó yẹ ká dáàbò bò wọ́n Dialogue: 0,0:02:02.81,0:02:04.37,Default,,0000,0000,0000,,Tún un ṣe Dialogue: 0,0:02:04.37,0:02:05.46,Default,,0000,0000,0000,,Apá tó pọ̀ jù lọ láyé yìí ti bà jẹ́. Dialogue: 0,0:02:05.46,0:02:06.22,Default,,0000,0000,0000,,Àmọ́ ó lè sọ ara rẹ̀ dọ̀tun Dialogue: 0,0:02:06.22,0:02:07.43,Default,,0000,0000,0000,,àwa náà lè ṣèrànwọ́ láti sọ àyíka wa di ọ̀tun Dialogue: 0,0:02:07.43,0:02:08.50,Default,,0000,0000,0000,, Dialogue: 0,0:02:08.50,0:02:09.51,Default,,0000,0000,0000,,Owó. Dialogue: 0,0:02:10.08,0:02:11.20,Default,,0000,0000,0000,,A ní láti jáwọ́ nínú nínáwó sórí ohun tó ń ba àyíká jẹ́ Dialogue: 0,0:02:11.20,0:02:13.32,Default,,0000,0000,0000,,ká náwó sórí ohun tó lè tú un ṣe. Dialogue: 0,0:02:13.32,0:02:16.15,Default,,0000,0000,0000,,kò jù bẹ́ẹ̀ lọ. Dialogue: 0,0:02:16.15,0:02:18.68,Default,,0000,0000,0000,,Dáàbò bò ó, tún un ṣe, nawo. Dialogue: 0,0:02:18.68,0:02:20.50,Default,,0000,0000,0000,,A lè ṣe bẹ́ẹ̀ kárí ayé Dialogue: 0,0:02:20.50,0:02:21.88,Default,,0000,0000,0000,,Ọ̀pọ̀ èèyàn ti ń lo igi, afẹ́fẹ́, àti àyíká láti wá ojútùú sọ́rọ̀ yìí Dialogue: 0,0:02:21.88,0:02:24.58,Default,,0000,0000,0000,,Gbogbo wa la gbọ́dọ̀ pawọ́ pọ̀ ṣe é. Dialogue: 0,0:02:24.58,0:02:26.58,Default,,0000,0000,0000,,Ìwọ náà lè kópa ńbẹ̀. Dialogue: 0,0:02:26.58,0:02:30.04,Default,,0000,0000,0000,,Dìbò fún àwọn tó ń gbèjà àyíká wa. Dialogue: 0,0:02:31.05,0:02:31.88,Default,,0000,0000,0000,,Pín fídíò yìí kiri. Dialogue: 0,0:02:32.70,0:02:36.17,Default,,0000,0000,0000,,Sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Dialogue: 0,0:02:36.17,0:02:38.41,Default,,0000,0000,0000,,Kárí ayé, àwọn èèyàn tí ò fẹ́ kí àyíká wa bà jẹ́ ń wọ́de lórí ọ̀rọ̀ yìí. Dialogue: 0,0:02:39.11,0:02:40.76,Default,,0000,0000,0000,,Tẹ̀ lé wọn! Dialogue: 0,0:02:40.76,0:02:42.02,Default,,0000,0000,0000,,Kò sóhun tó gbé. Dialogue: 0,0:02:42.02,0:02:43.04,Default,,0000,0000,0000,,Ohun tó o bá ṣe ò gbé.