0:00:01.560,0:00:04.135 Ọ̀rọ̀ ńlá rèé o 0:00:04.375,0:00:06.651 Orúkọ mi ni Greta Thunberg 0:00:06.852,0:00:10.212 Ní àkókò wa yìí, ọ̀pọ̀ nǹkan ti bẹ̀rẹ̀ sí í pa run 0:00:11.171,0:00:13.612 Afẹ́fẹ́ àti àyíká wa ń bà jẹ́ 0:00:14.022,0:00:18.217 Àwọn ọmọdé bíi tèmi pa ẹ̀kọ́ ìwé tì láti wọdé. 0:00:18.561,0:00:20.897 A ṣì lè tún ohun tó ti bà jẹ́ ṣe. 0:00:20.897,0:00:22.963 Ìwọ náà lè tún un ṣe. 0:00:23.372,0:00:26.577 Tá ò bá fẹ́ kí aráyé pa run, a gbọ́dọ̀ jáwọ́ nínú sísun epo rọ̀bì, àmọ́ ìyẹn nìkan ò tó. 0:00:27.217,0:00:29.822 Ọ̀pọ̀ àbá ni àwọn èèyàn ti dá, àmọ́ ojútùú kan wà fún wa. 0:00:30.112,0:00:32.692 wa 0:00:32.692,0:00:35.412 Ẹ jẹ́ kí ọ̀rẹ́ mi George ṣàlàyé. 0:00:35.682,0:00:38.112 Ẹ̀rọ ńlá kan wà tó máa ń fa èròjà carbon kúrò nínú afẹ́fẹ́, owó rẹ̀ ò pọ̀, ó sì máa ń tún 0:00:38.211,0:00:42.721 ara rẹ̀ ṣe 0:00:42.721,0:00:44.418 Òun là ń pè ní ... igi. 0:00:44.418,0:00:46.466 Igi jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó dá a jù láti fi tún afẹ́fẹ́ ṣe. 0:00:46.576,0:00:47.929 Àwọn igi ẹ̀gbà, koríko tó ti kú, igbó ńlá, ilẹ̀ pọ̀tọ̀pọ́tọ́, ìsàlẹ̀ òkun, igbó tí koríko bò, irà, òkìtì iyùn inú òkun 0:00:47.929,0:00:48.872 gbogbo wọn ló ń bá wa fa èròjà carbon kúrò nínú afẹ́fẹ́ 0:00:48.952,0:00:53.692 Igbó fúnra rẹ̀ ní ohun tó lè bá wa tún afẹ́fẹ́ tó ti bà jẹ́ ṣe. 0:00:53.692,0:00:56.502 Tá a bá jẹ́ kí igi àti afẹ́fẹ́ tún àyíká ṣe, àá rí ìyàtọ̀ ńlá. 0:00:56.502,0:00:58.772 Ìyẹn dáa, àbí bẹ́ẹ̀kọ́? 0:00:58.772,0:01:02.692 Kí ìyẹn tó lè ṣẹlẹ̀, àfi ká fi epo rọ̀bì sàyẹ̀ rẹ̀ nínú ilẹ̀. 0:01:03.212,0:01:07.883 Àmọ́ ohun to yani lẹ́nu ni pé ... a ò ṣe ohun tó yẹ ká ṣe 0:01:08.502,0:01:12.325 Owó tí à ń ná lórí ìrànwọ́ fún wíwa epo rọ̀bì fi ìlọ́po ẹgbẹ̀rún ju owó tá a fi ń wá 0:01:12.325,0:01:14.012 ojútùú lọ. 0:01:14.222,0:01:17.622 Ìdá méjì nínú ọgọ́rùn-ún péré là ń ná 0:01:19.702,0:01:21.892 nínú gbogbo owó ìrànwọ́ láti fi wá ojútùú sí afẹ́fẹ́ tó ń bà jẹ́. 0:01:21.892,0:01:24.402 0:01:25.744,0:01:30.548 Owó ẹ, owó orí ẹ àti èyí tí ò ń fi pa mọ́ wà lára owó yìí. 0:01:30.548,0:01:32.842 Ibi tí ọ̀rọ̀ wa ni pé ìsinsìnyí gan-an la nílò igi, afẹ́fẹ́ àti àyíká wa jù 0:01:32.842,0:01:35.377 àmọ́ ńṣe ni àwọn nǹkan yìí ń bà jẹ́ lọ́nà tó yára kánkán 0:01:35.377,0:01:39.053 Ó tó igba (200) ẹ̀dá abẹ̀mí tó ń pa run lójoojúmọ́ 0:01:39.394,0:01:41.021 Òkìtì yìnyín ńlá tó wà nípẹ̀kun ayé tí fẹ́rẹ̀ẹ́ yọ́ tán 0:01:41.021,0:01:43.468 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹranko inú igbó ti kú tán 0:01:43.773,0:01:44.958 Ọ̀pọ̀lọ̀pọ ilẹ̀ ló ti bà jẹ́. 0:01:44.958,0:01:47.211 Kí ló yẹ ká ṣe? 0:01:47.211,0:01:50.094 Kí ni ìwọ lè ṣe? 0:01:50.094,0:01:54.228 Kò le rárá ... a ní láti dáàbò ohun tó ń bà jẹ́, ká tún un ṣe, ká sì fowó ṣètìlẹ́yìn. 0:01:54.462,0:01:57.050 Dáàbò bò ó. 0:01:57.050,0:01:59.029 Iye àwọn igbó tó wà nílẹ̀ olóoru tí à ń gé 0:01:59.029,0:02:01.012 láàárín ìṣẹ́jú kan tó ọgbọ̀n (30) pápá bọ́ọ̀lù. 0:02:01.012,0:02:02.813 Àwọn igbó yìí ń ṣe wá lóore, ó yẹ ká dáàbò bò wọ́n 0:02:02.813,0:02:04.374 Tún un ṣe 0:02:04.374,0:02:05.458 Apá tó pọ̀ jù lọ láyé yìí ti bà jẹ́. 0:02:05.458,0:02:06.225 Àmọ́ ó lè sọ ara rẹ̀ dọ̀tun 0:02:06.225,0:02:07.429 àwa náà lè ṣèrànwọ́ láti sọ àyíka wa di ọ̀tun 0:02:07.429,0:02:08.501 0:02:08.501,0:02:09.513 Owó. 0:02:10.084,0:02:11.198 A ní láti jáwọ́ nínú nínáwó sórí ohun tó ń ba àyíká jẹ́ 0:02:11.198,0:02:13.325 ká náwó sórí ohun tó lè tú un ṣe. 0:02:13.325,0:02:16.153 kò jù bẹ́ẹ̀ lọ. 0:02:16.153,0:02:18.679 Dáàbò bò ó, tún un ṣe, nawo. 0:02:18.679,0:02:20.505 A lè ṣe bẹ́ẹ̀ kárí ayé 0:02:20.505,0:02:21.878 Ọ̀pọ̀ èèyàn ti ń lo igi, afẹ́fẹ́, àti àyíká láti wá ojútùú sọ́rọ̀ yìí 0:02:21.878,0:02:24.581 Gbogbo wa la gbọ́dọ̀ pawọ́ pọ̀ ṣe é. 0:02:24.581,0:02:26.581 Ìwọ náà lè kópa ńbẹ̀. 0:02:26.581,0:02:30.042 Dìbò fún àwọn tó ń gbèjà àyíká wa. 0:02:31.051,0:02:31.881 Pín fídíò yìí kiri. 0:02:32.702,0:02:36.172 Sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. 0:02:36.172,0:02:38.412 Kárí ayé, àwọn èèyàn tí ò fẹ́ kí àyíká wa bà jẹ́ ń wọ́de lórí ọ̀rọ̀ yìí. 0:02:39.112,0:02:40.756 Tẹ̀ lé wọn! 0:02:40.756,0:02:42.018 Kò sóhun tó gbé. 0:02:42.018,0:02:43.044 Ohun tó o bá ṣe ò gbé.